Ní ilẹ̀ Nàìjíríà, kò sí ìgbàláàyè fún oyún ṣíṣẹ́ àyàfi tí ẹ̀mí aláboyún bá wà nínú ewu. Òfin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì ni ó wà fún oyún ṣíṣẹ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà, ọkàn ní apá àríwá, ọkàn ní gúúsù. Òfin apá gúúsù faramọ́ ọ tí oyún náà bá lè pa àlàáfíà ara àti ọpọlọ aláboyún lára. Àwọn Mùsùlùmí ni ó pọ̀ jù ní apá àríwá tí ó sì jẹ́ pé òfin kóòdù ìjìyà tí a mọ̀ sí “penal code”, tí wọ́n sì ń lo òfin kóòdù tí a mọ̀ sí “criminal code” ní apá gúúsù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti jẹ́ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́.
Ní ọdún 1982, ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí àti àwọn tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn àrùn tí ó ń gbógun ti àwọn ẹ̀yà ara obìnrin tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí fi ọwọ́ s í ìwé òfin tí yóò fi kún àwọn ohun tí ó lè fa ìgbàláàyè oyún ṣíṣẹ́. Ìwé òfin yìí ò bá fi ààyè gba ṣíṣẹ́ oyún tí ó bá lè kóbá àlàáfíà àwọn ọmọ tí aláboyún náà ti bí tẹ́lẹ̀ tàbí tí ó ṣeéṣe kí ó fi oyún náà bí ọmọ alaábọ̀ ara tàbí tí ọpọlọ rẹ kò ní dápé ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àti àjọ àwọn ẹgbẹ́ obìnrin ní ilẹ̀ Nàìjíríà takò ó. Wọ́n ní yóò fa ìfẹ́kúfẹ́ àti ìranù nínú àwùjọ. Títí di òní, kò sí ìyípadà kankan nínú òfin tí ó de oyún ṣíṣẹ́.
Kí ni àwọn ìtọ́jú tí ó wà fún aláboyún lẹ́yìn oyún ṣíṣẹ́ nílẹ́ Nàìjíríà?
Àwọn ọ̀nà tí ó jẹ mọ́ ìṣègùn òyìnbó: Lílo àwọn òògùn bíi misoprostol (lábẹ́ orúkọ Cycotec, Miso Fem, Vanprazol-200)
Àwọn ọ̀nà tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ abẹ: Fífa oyún síta (Manual vacuum Aspiration)
Àwọn wo ni ó lè bá ènìyàn ṣẹ́ oyún, tí ó sì lè ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ fún un ní ọ̀nà tí ó bófin mu ni ilẹ̀ Nàìjíríà?
Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera tí wọ́n ní ìwé àṣẹ, ní ilé ìwòsàn ìjọba tàbí aládàáni nìkan ni òfin fààyè gbà láti ṣẹ́ oyún àti láti ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́.
Àkíyèsí:
Òfin fi ààyè gba elétò ìlera láti kọ̀ láti ṣẹ́ oyún tí ẹ̀sìn, àṣà, ìṣe tàbí ìwà wọn ò bá rọ̀ mọ́ ọ.
Níbo ni mo lè lọ láti ṣẹ́ oyún àti láti gba ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ ní ọ̀nà tí ó bófin mu?
Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera tí ó ní ìwé àṣẹ nìkan ni òfin fààyè gbà láti ṣẹ́yún àti láti ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́. O lè rí wọn ní ilé ìwòsàn ìjọba tàbí ti aládàáni tí ìjọba fi ọwọ́ sí.
Àkíyèsí:
Àwọn elétò ìlera kọ̀lọ̀rọ̀sí tí kò kọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí kò sì ní ìwé àṣẹ náà máa ń ṣẹ́ oyún tàbí ṣe ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí ó yíwọ́. Jọ̀wọ́, lọ sí ọ̀dọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ààbò tí ó ní ìwé àṣẹ tí ó bá fẹ́ ṣẹ́yún.
Èló ni a lè ṣẹ́yún tàbí gba ìtọ́jú ẹ̀yìn oyún ṣíṣẹ́ ní ọ̀nà tí kò béwu dé ní ilẹ̀ Nàìjíríà?
Owó oyún ṣíṣẹ́ àti ìtọ́jú ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń yàtọ̀. Ìyàtọ̀ yìí máa ń dá lórí irú ilé ìwòsàn tí ó jẹ́ (ti ìjọba tàbí aládàáni), elétò ààbò tí ó bá jẹ́, ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà (òògùn lílò tàbí iṣẹ́ abẹ), ewu tí ó bá dé, àti bí àwọn àpẹẹrẹ náà bá ṣe le tó. Owo náà lè wà láàrin dọ́là mẹ́ta sí mẹ́tàlẹ́lọ́gọ́rùn ún (USD3.00 – USD103.00).
Irú òògùn oyún ìṣẹ́yún àti ìtọ́jú ẹ̀yìn rẹ̀ wo ni ó wà ní Nàìjíríà?
Misoprostol wà (lábẹ́ àwọn orúkọ bíi Cycotec, Miso-fem àti Vanaprazol-200.
Mifepristone náà wà ní àpapọ̀ pẹ̀lú orúkọ Mifepack.
Àkíyèsí:
Ohun tí ààyè lílo misoprostol wà fún ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni láti fi dá ẹ̀jẹ̀ ìbímọ dúró ṣùgbọ́n ó lè fi ṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó láìsí wàhálà tí oyún náà ò bá tíi ju ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá lọ tí ó sì tẹ̀lé ọ̀nà tí a là kalẹ̀.
Ǹjẹ́ mo lè ra òògùn oyún ṣíṣẹ́ ní àwọn ilé ìtajà òògùn ní Nàìjíríà?
O lè ra Misoprostol lábẹ́ orúkọ Cycotec ní àwọn ilé ìtajà òògùn tí ó bá ní ìwé ìjúwe láti ọ̀dọ̀ elétò ààbò.
Owo rẹ ò ju dọ́là mẹ́ta sí mẹ́sàn-án lọ (USD3.00 – USD9.00)
Àkíyèsí:
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùtajà òògùn máa ń ta misoprostol láìsí ìwé ìjúwe yìí ṣùgbọ́n wọn ò ní sọ ẹni tí ó lè lò ó, bí wọn ó ṣe lò ó àti iye tí wọn ó lò. Jọ̀wọ́, lọ sí https://www.howtouseabortionpill.org/howto/ fún àlàyé kíkún nípa bí a ṣe ń lo òògùn ìṣẹ́yún.
Ta ni mo lè kàn sí fún àlàyé síwájú síi nípa oyún ṣíṣẹ́ àti ìtọ́jú ní ilẹ̀ Nàìjíríà?
Ms Rosy Hotline – máa ń ṣe àlàyé nípa ìlera àti ẹ̀tọ́ tí ó jẹ mọ́ ọmọ bíbí àti ìbálòpọ̀ fún àwọn obìnrin. O lè pe aago wọn ní ìgbàkigbà tí o bá fẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́. Pe: +1855 553 1550 OR 08097737600 OR 08097738001 Facebook:https://web.facebook.com/msrosyhotline/?_rdc=1&_rdr