À ń pèsè àlàyé àìléwu nípa òògùn ìsẹ́yún

Bí a ṣe jẹ́

HowToUseAbortionPill jẹ́ àwùjọ orí ayélujára tí àwọn olùfarajìn tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó yẹ kí gbogbo ènìyàn pátápátá ní àǹfààní láti ṣẹ́ oyún lọ́nà tí kò léwu, ibi yòówù kí wọ́n máa gbé, gbé kalẹ̀

about us

Ohun tí à ń ṣe.

HowToUseAbortionPill ń ṣiṣẹ́ láti fọnrere òkodoro ọ̀rọ̀ àti ohun ìrànwọ́ nípa òògùn ìṣẹ́yún – ohun tí ó gbọ́dọ̀ wò kí o tó ṣe é, ibi tí ó ti lè rí ojúlówó òògùn ìṣẹ́yún, bí o ṣe lè lò ó láìsí ewu, ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ àti ìgbà tí o yẹ láti béèrè fún ìtọ́jú. Ohun tí a wà fún ni láti kọ́ àwọn obìnrin nípa ọ̀nà tí wọ́n lè fi ṣẹ́ oyún fúnraawọn ní ọ̀nà tí ó rọ̀ wọ́n lọ́rùn.

Ibi tí a ti ń ṣiṣẹ́.

HowToUseAbortionPill jẹ́ àjọ àgbáyé – a wà láti pèsè àlàyé àti ohun ìrànwọ́ fún àwọn obìnrin káàkiri àgbáyé. A ní àpèrè orí ayélujára tí a túmọ̀ sí èdè 26. Ǹjẹ́ o nílò èdè kan tí kò sí níbẹ̀? Kàn sí wa ni info@howtouseabortionpill.org

Ìkọ̀tì

Gbogbo ipá wa ni a sà láti ríi pé gbogbo ohun tí ó wà ní orí àpèrè yìí jẹ́ òdodo. Síbẹ̀ síbẹ̀, ó ṣeéṣe kí àwọn nǹkankan yí padà látìgbàdégbà. Kò sí ẹ̀bí lọ́wọ́ àwọn alákóso àpèrè yìí fún bí àlàyé kan ṣe dájú tó ní àkókò tí ó wà níbẹ̀.

Itọkasi

Àwọn òǹkọ̀wé:

  • Gbogbo àkóónú tí a fihàn lórí ayélujára yìí ni a kọ nípa ẹgbẹ́ HowToUseAbortionPill.org ní ìbámu pẹ̀lu àwọn òṣùwọ̀n àti ìlànà láti Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ [The National Abortion Federation], Ipas, Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé [the World Health Organization], DKT L’ágbàyé àti carafem.
  • Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ (NAF) jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àwọn olùpèsè oyún ṣíṣẹ́ ní Àríwá Amẹ́ríkà, àti aṣíwájú ní ìgbìyànjú fún yíyàn láti yọ oyún. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2020 Àwọn ìtọ́ni Òfin Ìṣègùn tí NAF gbéjáde.
  • Ipas jẹ́ ẹgbẹ́ kansoso ní àgbàyé tí ó ńtẹjúmọ́ mímú kí rírí ààyè sí oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu àti àbójútó dídènà oyún níní fẹ̀ si. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu Ìmúdójú-ìwọ̀n Ìléra Bíbímọ 2019 tí Ipas gbéjáde.
  • Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé (WHO) jẹ́ àjọ tí ó mọ nǹkan lámọ̀já ti ẹ̀ka Àjọ Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè L’ágbàyé tí ó ní ojúṣe fún ìlera àwùjọ l’ágbàyé. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2012 Oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu: ìtọ́ni iṣẹ́ ọnà àti òfin fún ètò ìlera tí WHO gbéjáde.
  • DKT L’ágbàyé jẹ́ àjọ tí a ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, tí kò sí fún èrè tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1989 láti tẹjúmọ́ agbára ìlànà mímú àwùjọ yípadà fún àǹfààní àwùjọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣe àìní tí ó gá jù lọ fún fífi ètò sí ọmọ bíbí, dídènà HIV/AIDS àti oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu.
  • carafem jẹ́ alátagbà ìṣègùn tí ó ńpèsè oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu èyìtí ó rọrùn àti fífi ètò sí ọmọ bíbí nípasẹ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ṣe àkóso iye àwọn ọmọ àti àlàfo tí ó wà láàrín wọn.