Lẹhin Lílò Àwọn Òògùn Ìsẹ́yún

Ọ̀nà méjì ni o lè gbà ṣẹ́yún ní ìlànà ìlera- Mifepristone àti Misoprostol tàbí Misoprostol nìkan. Méjèèjì ni ó sì máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Àwọn ìrírí àti ìṣẹlẹ̀ lágọ̀ọ́ ara le yàtọ̀ tí o bá lo òògùn yìí.

Kini Àwọn Ìmọ̀lára Lẹ́yìn Tí ó Bá Lọ Óògùn Ìsẹ́yún?
Kí ni àwọn àmì tí ó lè fihàn pé nǹkan fẹ́ máa le?
After Use Pills

Kini Àwọn Ìmọ̀lára Lẹ́yìn Tí ó Bá Lọ Óògùn Ìsẹ́yún?

Lẹ́yìn Tí O Bá Lọ Mifepristone

Mifepristone leè fa kí ẹ̀jẹ̀ jáde lójú ara fẹ́rẹ́fẹ́. Síbẹ̀ síbẹ̀, kò sí ewu kí kò bá sí ẹ̀jẹ̀.

Lẹ́yìn Tí O Bá Lo Misoprostol:

Inú rírun àti ẹ̀jẹ̀ yíyọ ni ó wọ́pọ̀ jù. Àwọn àmì yìí sì wúlò nítorí pé wọ́n ń fihàn pé òògùn náà ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n báwo ni ìrora inú rírun àti ẹ̀jẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó?

Fún àwọn kan, ìrora inú rírun yìí máa ń pọ̀ gàn – ó máa ń le ju ti ìgbà nǹkan oṣù lọ (fún ẹni tí ó bá máa ń inú rírun nkan oṣù)

Fún àwọn kan, ẹ̀jẹ̀ náà máa ń pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ. Ó wọ́pọ̀ kí ẹ̀jẹ̀ dídì yọ lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọn bá lo misoprostol. Iye ọ̀sẹ̀ tí oyún náà jẹ́ ni yóò sọ bí ẹ̀jẹ̀ dídì náà yóò ṣe tóbi tó.

Fún àwọn mìíràn, ìrora inú rírun náà kò ní kọjá àfaradà, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ náà ò ní pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ.

Má ṣe jáyà tí ẹ̀jẹ̀ àti ìrora inú rírun bá pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ.

Tí ìrora inú rírun náà bá pọ̀ jù, ó lè lo ibuprofen. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè, o lè ra ibuprofen (200mg) láìjẹ́ pé dókítà kọ ọ́ fún ọ. Lo 3 sí 4 (ọ̀kọ̀ọ̀kan, 200mg) lẹ́yìn wákàtí 6 sí 8 sí ara wọn.

Ó lè jẹ, kí o sì mu bí ó ṣe wù ọ́.

Wà ní ibi tí ó fọkànbalẹ títí ara rẹ yóò fi balẹ̀.

Ara ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin máa ń bọ́ sí ipò láàrin wákàtí 24.

Àkíyèsí:

Tí o bá ṣe àyẹ̀wò lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ 3 si 4 tí o ṣẹ́yún, àyẹ̀wò yóò sì fi hàn pé o lóyún nítorí àwọn hòmóònù tí ó ṣì wà lára rẹ, ó si le wà bẹ fún bi ọ̀sẹ̀ mẹ́fà síi. Tí àwọn àmì pé o lóyún (àárẹ̀ ara, ọyàn rírọ̀, inú rírú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) bá sì ń yọ ọ́ lẹ́nu lẹ́yìn tí o lo òògùn ìṣẹ́yún, lọ rí dókítà fun ayewo to daju.

Àwọn Àmì Lẹ́yìn Lílo Òògùn Ìsẹ́yún àti Àwọn Ipa Òògùn Ìsẹ́yún

Tí oyún bá ń wálẹ̀, àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí kò mú ewu lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n má ṣe sàsùn para. Nǹkan lè ti fẹ́ yíwọ́ tí ó ba rí àwọn àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ wọ̀nyí:

Ẹ̀jẹ̀ tí ó ń dà yàà:

Tí ẹ̀jẹ̀ bá kún páàdì 2 láàrin wákàtí méjì lẹ́yìn tí o lérò pé oyún náà ti wálẹ̀, o ní láti rí elétò ìlera ní kíákíá nítorí ẹ̀jẹ̀ náà ti pọ̀jù. Kí ẹ̀jẹ̀ kún páàdì túmọ̀ sí pé páàdì náà kún fún ẹ̀jẹ̀ láti iwájú dé ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ sí ẹ̀gbẹ́, àti dénú.

Ìrora púpọ̀.

Tí ìrora náà bá pọ̀ tí òògùn ibuprofen ò sì kápá rẹ, béèrè fún ìtọ́jú. Irú ìrora báyìí lè wáyé tí nǹkan bá ṣe oyún náà. A gba aláboyún tí ó bá ń jẹ ìrora tí apá ibuprofen ò ká láti rí elétò ìlera nítorí ó léwu. A gba àwọn ènìyàn tí ń jẹ ìrora níyànjú pé kí wọn rí elétò àbò.

Àárẹ̀ ara líle

Ara rẹ lè máa gbóná, kí inú rẹ máa ru tàbí kí o máa bì ní ọjọ́ tí o bá lo misoprostol. Má bẹ̀rù. Lẹ́yìn èyí, ó yẹ kí ara rẹ máa yá síi ni. Ṣùgbọ́n tí ó bá ń rẹ ọ síi, yára lọ rí dókítà.

Àwọn Òǹkọ̀wé:

  • Gbogbo àkóónú tí a fihàn lórí ayélujára yìí ni a kọ nípa ẹgbẹ́ HowToUseAbortionPill.org ní ìbámu pẹ̀lu àwọn òṣùwọ̀n àti ìlànà láti Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ [The National Abortion Federation], Ipas, Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé [the World Health Organization], DKT L’ágbàyé àti carafem.
  • Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ (NAF) jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àwọn olùpèsè oyún ṣíṣẹ́ ní Àríwá Amẹ́ríkà, àti aṣíwájú ní ìgbìyànjú fún yíyàn láti yọ oyún. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2020 Àwọn ìtọ́ni Òfin Ìṣègùn tí NAF gbéjáde.
  • Ipas jẹ́ ẹgbẹ́ kansoso ní àgbàyé tí ó ńtẹjúmọ́ mímú kí rírí ààyè sí oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu àti àbójútó dídènà oyún níní fẹ̀ si. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu Ìmúdójú-ìwọ̀n Ìléra Bíbímọ 2019 tí Ipas gbéjáde.
  • Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé (WHO) jẹ́ àjọ tí ó mọ nǹkan lámọ̀já ti ẹ̀ka Àjọ Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè L’ágbàyé tí ó ní ojúṣe fún ìlera àwùjọ l’ágbàyé. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2012 Oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu: ìtọ́ni iṣẹ́ ọnà àti òfin fún ètò ìlera tí WHO gbéjáde.
  • DKT L’ágbàyé jẹ́ àjọ tí a ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, tí kò sí fún èrè tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1989 láti tẹjúmọ́ agbára ìlànà mímú àwùjọ yípadà fún àǹfààní àwùjọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣe àìní tí ó gá jù lọ fún fífi ètò sí ọmọ bíbí, dídènà HIV/AIDS àti oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu.
  • carafem jẹ́ alátagbà ìṣègùn tí ó ńpèsè oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu èyìtí ó rọrùn àti fífi ètò sí ọmọ bíbí nípasẹ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ṣe àkóso iye àwọn ọmọ àti àlàfo tí ó wà láàrín wọn.

Àwọn Itọkasi:

HowToUseAbortionPill.org nÍ àjǫșepǫ pèlu ilé isé tí a kò dá sílè fún èrè, èyìtí ó wà ní orílé ède Améríkà.
HowToUseAbortionPill.org ń se wà fún ìmò nìkan, won kò ní àjosepò pèlú ilé isé ìlera rárá.

    Women First Digital ló sagbátẹrù ẹ̀.