Bi o ṣe lè Lo òògùn Ìsẹ́yún

Oríṣi òògùn méjì ló wà fún ìséyún: Mifepristone àti misoprostol. Oyún sísé pèlú òògùn ń sisé dáada tí a bá lo àwon òògùn méjèjì yìí papò. Síbẹ̀, tí Mifepristone kò bá sí, misoprostol nìkan náà lé sisé láti séyún lónà àìléwu.

Pinu bóyá o fé láti kó nípa àwon òògùn ìsẹ́yún ní ònà tí kò panilára nípa lílo Mifepristone àti misoprostol papò tàbí nípa lílo misoprostol nìkan.

Mifeprisitóònù àti Mísópròsìtóòlù
Mísópròsìtóòlù nìkan
How to Use

Kí o tó bèrè, ka àwọn ìyànjú wa lórii Kí o tó lo àwon òògùn . Rí àrídájú:

Àwon Ílànà Fún Oyún Ṣíṣẹ́ kan Nípa Lílo Mifepristone àti Misoprostol

Fún ìséyún nípa lílo Mifepristone àti misoprostol, wàá nílò láti lo Mifepristone eyòkan èyí tí ó jé 200mg àti mérin sí méjo misoprostol èyítí ó jé 200mcg. Wàá tún fé ní òògùn araríro lọ́wọ́ bíi Ibuprofen láti dékùn araríro. Òògùn Acetaminophen àti paracetamol kìí sisé fún ìrora nígbà ìséyún, nítorínáà a kò gbà yín níyànjú láti lo àwon òògùn náà.

Báyì ni a se lè lo Mifepristone àti Misoprostol papò láti séyún:

Ìpele 1:

Gbé Mifepristone eyòkan èyí tí ó jé 200mg mì pèlú omi.

Ìpele 2:

Dúró fún wákàtí 24 sí 48.

Ìpele 3:

Fi misoprostol 4 (èyítí ó jé 200mcg) sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ìséjú 30 bí wón se ń túká. Ìwo kò gbodò sòrò tàbí jeun fún ìséjú 30 yìí, nítorínáà ó dára kí o wà ní ibi tí ó dáké tí enikéni kò ní yo é lénu. Léyìn ìséjú 30, mu omi díè kí o sì gbé òògùn èyítí ó kù mì. Èyí tún jé àsìkò tó dára láti lo òògùn araríro bíi ibuprofen, nítoríwípé inú rírun náà yó bèrè láìpé.

Ó ye kí ojú ara rẹ bèrè sí sẹ̀jẹ̀ àti inú rírun láàrin wákàtí 3 léyìn tí o bá ti lo misoprostol 4 náà.

Ípele 4:

Léyìn wákàtí 24 tí o ti lo òògùn misoprostol 4 náà, tí o kò bá rí èjè tàbí tí kò bá dá e lójú wípé oyún náà ti ṣẹ́, fi òògùn misoprostol 4 míràn sí abé ahón re. Fi wón sílè síbè fún ìséjú 30 bí wón se ń túká. Léyìn ìséjú 30, mu omi díè kí o sì gbé òògùn èyítí ó kù mì.

Àwon Àkíyèsí Míràn Fún Síséyún Pèlú Mifepristone àti Misoprostol

Kó nípa ohun tí ó ye kí o retí léyìn tí o bá lo mifeprisitóònù àti mísópròsìtóòlù níbí.

Tí o bá ni inú rírun tó pò tóbẹ́ẹ̀gẹ́, Ibuprofen jé òògùn tí ó dára láti farada ìrora. O lè ra Ibuprofen èyítí ó ní agbára 200mg láti ilé ìtòògùn (láìní ìwé láti òdo dókítà) ní òpòlopò orílé èdè. Lo 3 sí 4 (èyítí ó jé 200mg) ní gbogbo wákàtí 6 sí 8. Tí o bá nílò ohun kan síi láti dín ìrora kù, o tún lè lo òògùn Tailenólù méjì (èyítí ó jé 325mg) ní gbogbo wákàtí 6 sí 8.

Tí ohun kan bá rú e lójú nípa Ílànà ìséyún náà tí o sì fé ìrànlówó, o lè késí àwon òre wa ní orí èro ayélujára www.safe2choose.orgwww.womenhelp.org tàbí www.womenonweb.org.

Tí o bá lo àwon òògùn ìséyún náà Mifepristone àti Misoprostol, kò pidandan kí o lo rí onímò ìlera fún àyèwò ìtèsíwájú. Àwon òògùn yìí múnádóko tóbẹ́ẹ̀gẹ́ tí ìgbìmọ̀ ìlera àgbáyé tí à ń pè ní ajo World Health Organization pàse wípé ohun tí ó lè mú kí o lo fún àyèwò ìtèsíwájú ni:

  • Ara re kò dá, tàbí tí ìrora re kò dínkù léyìn ojó 2 tàbí 3. Tí èyí bá selé, wa ìtójú ìlera lésèkesè.
  • O sí ń ní àwon ààmì wípé oyún wà lára re léyìn òsè 2 tí o ti lo òògùn ìséyún náà.
  • Èjè tí ó ń jáde láti ojú ara re pò gidigan kò dè dínkù léyìn òsè 2.

Àwon Ílànà Fún Oyún Ṣíṣẹ́ pẹ̀lú Misoprostol nìkan

Kí o tó bèrè, ka àwọn ìyànjú wa lórii Kí o tó lo àwon òògùn Rí àrídájú:

Ti Mifepristone kò bá wà ní agbègbè re, o lè lo Misoprostol nìkan láti séyún.

Fún ìséyún nípa lílo Mifepristone àti misoprostol, wàá nílò láti lo Mifepristone eyòkan èyí tí ó jé 200mg àti mérin sí méjo misoprostol èyítí ó jé 200mcg. Wàá tún fé ní òògùn araríro lọ́wọ́ bíi Ibuprofen láti dékùn araríro. Òògùn Acetaminophen àti paracetamol kìí sisé fún ìrora nígbà ìséyún, nítorínáà a kò gbà yín níyànjú láti lo àwon òògùn náà.

Báyì ni a se lè lo Misoprostol nìkan láti séyún:

Ìpele 1:

Fi misoprostol 4 (èyítí ó jé 200mcg) sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ìséjú 30 bí wón se ń túká. Ìwo kò gbodò sòrò tàbí jeun fún ìséjú 30 yìí, nítorínáà ó dára kí o wà ní ibi tí ó dáké tí enikéni kò ní yo é lénu. Léyìn ìséjú 30, mu omi díè kí o sì gbé òògùn èyítí ó kù mì. Èyí tún jé àsìkò tó dára láti lo òògùn araríro bíi ibuprofen, nítoríwípé inú rírun náà yó bèrè láìpé.

Ó ye kí ojú ara rẹ bèrè sí sẹ̀jẹ̀ àti inú rírun láàrin wákàtí 3 léyìn tí o bá ti lo misoprostol 4 náà.

Ìpele 2:

Dúró fún wákàtí 3.

Ìpele 3:

Fi Misoprostol 4 míràn (èyítí ó jé 200mcg) sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ìséjú 30 kí wón fi túká

Ípele 4:

Dúró fún wákàtí 3 míràn.

Ìpele 5:

Fi Misoprostol 4 míràn sí abé ahón re kí o sì fi wón sílè síbè fún ìséjú 30 kí wón fi túká.

Ó ye kí ojú ara rẹ bẹ̀rẹ̀ sí sẹ̀jẹ̀ àti inú rírun nígbàtí o bá ń lo òògùn náà. Ríi dájú wípé o lo gbogbo òògùn 12 náà bótilè jè wípé o ti bèrè síní rí èjè láti ojú ara rẹ kí ó tó lo gbogbo òògùn náà tán.

Àwon Àkíyèsí Míràn Fún Síséyún pèlú Misoprostol:

Kó nípa ohun tí ó ye kí o retí léyìn tí o bá lo Misoprostol níbí.

Tí o bá ni inú rírun tó pò tóbẹ́ẹ̀gẹ́, Ibuprofen jé òògùn tí ó dára láti farada ìrora. O lè ra Ibuprofen èyítí ó ní agbára 200mg láti ilé ìtòògùn (láìní ìwé láti òdo dókítà) ní òpòlopò orílé èdè. Lo 3 sí 4 (èyítí ó jé 200mg) ní gbogbo wákàtí 6 sí 8. Tí o bá nílò ohun kan síi láti dín ìrora kù, o tún lè lo òògùn Tailenólù méjì (èyítí ó jé 325mg) ní gbogbo wákàtí 6 sí 8.

Tí ohun kan bá rú e lójú nípa Ílànà ìséyún náà tí o sì fé ìrànlówó, o lè kànsí àwon òre wa ní orí èro ayélujára www.safe2choose.orgwww.womenhelp.org tàbí www.womenonweb.org.

Tí o bá lo àwon òògùn ìséyún náà Mifepristone àti Misoprostol, kò pidandan kí o lo rí onímò ìlera fún àyèwò ìtèsíwájú. Àwon òògùn yìí múnádóko tóbẹ́ẹ̀gẹ́ tí ìgbìmọ̀ ìlera àgbáyé tí à ń pè ní ajo World Health Organization pàse wípé ohun tí ó lè mú kí o lo fún àyèwò ìtèsíwájú ni:

  • Ara re kò dá, tàbí tí ìrora re kò dínkù léyìn ojó 2 tàbí 3. Tí èyí bá selé, wa ìtójú ìlera lésèkesè.
  • O sí ń ní àwon ààmì wípé oyún wà lára re léyìn òsè 2 tí o ti lo òògùn ìséyún náà.
  • Èjè tí ó ń jáde láti ojú ara re pò gidigan kò dè dínkù léyìn òsè 2.

Àwọn òǹkọ̀wé:

  • Gbogbo àkóónú tí a fihàn lórí ayélujára yìí ni a kọ nípa ẹgbẹ́ HowToUseAbortionPill.org ní ìbámu pẹ̀lu àwọn òṣùwọ̀n àti ìlànà láti Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ [The National Abortion Federation], Ipas, Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé [the World Health Organization], DKT L’ágbàyé àti carafem.
  • Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ (NAF) jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àwọn olùpèsè oyún ṣíṣẹ́ ní Àríwá Amẹ́ríkà, àti aṣíwájú ní ìgbìyànjú fún yíyàn láti yọ oyún. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2020 Àwọn ìtọ́ni Òfin Ìṣègùn tí NAF gbéjáde.
  • Ipas jẹ́ ẹgbẹ́ kansoso ní àgbàyé tí ó ńtẹjúmọ́ mímú kí rírí ààyè sí oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu àti àbójútó dídènà oyún níní fẹ̀ si. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu Ìmúdójú-ìwọ̀n Ìléra Bíbímọ 2019 tí Ipas gbéjáde.
  • Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé (WHO) jẹ́ àjọ tí ó mọ nǹkan lámọ̀já ti ẹ̀ka Àjọ Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè L’ágbàyé tí ó ní ojúṣe fún ìlera àwùjọ l’ágbàyé. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2012 Oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu: ìtọ́ni iṣẹ́ ọnà àti òfin fún ètò ìlera tí WHO gbéjáde.
  • DKT L’ágbàyé jẹ́ àjọ tí a ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, tí kò sí fún èrè tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1989 láti tẹjúmọ́ agbára ìlànà mímú àwùjọ yípadà fún àǹfààní àwùjọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣe àìní tí ó gá jù lọ fún fífi ètò sí ọmọ bíbí, dídènà HIV/AIDS àti oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu.
  • carafem jẹ́ alátagbà ìṣègùn tí ó ńpèsè oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu èyìtí ó rọrùn àti fífi ètò sí ọmọ bíbí nípasẹ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ṣe àkóso iye àwọn ọmọ àti àlàfo tí ó wà láàrín wọn.

Àwọn Itọkasi: