Ṣíṣẹ́ Oyún Ní Ìlànà Ìlera

Ṣíṣẹ́ oyún ní ìlànà ìlera, tí a tún mọ̀ sí ṣíṣẹ́ oyún ní ìlànà ìsègùn ma ń ṣẹlẹ̀ tí a bá lo òògùn ìsẹ́yún láti yọ oyún. O lè lo òògùn ìsẹ́yún ní ìlànà ìlera Mifepristone papọ̀ pẹ̀lú misoprostol, tàbí misoprostol nìkan. O lè lo òògùn yìí nípa fífi ṣojú ara tàbí abẹ ahọ́n. Sibẹsibẹ, à má ń gba ìyànjú abẹ ahọ́n kì àfihàn má ba à hàn. Àjọ World Health Organization ṣe àkójọpọ̀ ṣíṣẹ́ oyún ní ìlànà ìlera gẹ́gẹ́bí ìlànà ìtọ́jú ara ẹni tí kò nílò àmòjútó oníṣègùn. Èyí túmọ̀ sí pé o lè ṣe ìtọ́jú ara rẹ nínú ilé. Àwọn ìlànà HowToUseAbortionPill wà fún oyún tí kò kọjá ọ̀sẹ̀ 13.

About Medical Abortion
How it Works Abortion Pills

Bawo ni awon òògùn ìsẹ́yún ṣe ń ṣisẹ́

Mifepristone ń dá ìtẹ̀síwájú oyún dúró láti máa dàgbà ó sì ń ṣe ìrànlówọ́ láti sí ojú ara(àbáwọlé ilé ọmọ). Misoprostol má ń jẹ kí ojú ara fún pọ̀, tí yíò sì padà ti oyún náà jáde.

Lọ́gọ́n tí Misoprostol bá tí yòrò sínú ara, inú rírun àti ẹ̀jẹ̀ yíò bẹ̀rẹ̀. Èyí sì má ń bẹ̀rẹ̀ láàrin wákàtí kan sí méjì lẹ́yìn ìlò àwọn ògùn àkọ́kọ́. Oyún ṣíṣẹ́ yìí má ń wáyé láàárín wákàtí 24 lẹ́yìn ìlò àwọn ògùn misoprostol ìkẹyìn. Nígbà míràn ó má ń wá yé ṣáájú àwọn wọ̀nyí.

Ti O ba jẹ Ifiyesi

Àwọn wọ̀nyí ní ọ̀nà tí a lè fi mọ pé oyún náà ti ṣẹ́.

  • Ó lè dá àwọn àwọn nkan oyún mọ tí wọn bá ń jáde lójú ara. Ó le rí bí ẹ̀jẹ̀ dúdú pẹ̀lú awọ fẹ́lẹ́ fẹ́lẹ́, tàbí àpò kékeré tó ní àwo funfun, awo fẹ́lẹ́ fẹ́lẹ́. Bí oyún náà ṣe pẹ́ sí ní, ó le kéré ju èékánná tàbí kó tóbi tó àtàǹpàkò.
  • Ẹ̀jẹ̀ yíyọ ní àsìkò ìsẹ́yún má ń fara pẹ́ tí nkan oṣù tàbí kó ju bẹẹ lọ.
  • Àwọn Ìmọ̀lára oyún leè dàgbà. Bíi irúfẹ́ ọyàn ríro, èébì, and àárẹ̀ yíò bẹ̀rẹ̀ sí yàtọ̀ ní dáadáa.

Itọkasi: