Ara-isakoso ti Iṣẹyun

Ẹkọ ori ayelujara yii jẹ apẹrẹ fun ẹnikẹni ti n wa lati ni imọ siwaju sii nipa iṣẹyun iṣakoso ara-ẹni, tabi nini iṣẹyun ni ile. Pẹlu alaye ti iwọ yoo kọ ninu ẹkọ yii, o le ṣe iranlọwọ lati rii daju pe iṣẹyun pẹlu awọn oogun jẹ ailewu, wiwọle, ati aabo. Ẹkọ yii jẹ iṣelọpọ ni ifowosowopo laarin Médecins Sans Frontières ati www.HowToUseAbortionPill.org

Èkó Ìkíní Sé mo ti lóyún?

O fé mò bóyá o lóyún bí? Wo fídíò yìí fún àlàyé tó níse pèlú àrídájú oyún níní

Oyún, oyún níní

Oyún – èyí tí a gbèrò àti èyí tí a kò gbèrò- jé ìrírí tí ó wópò

Káàkiri àgbáyé, púpò ju ogójì oyún ní àgbáyé ni a kò gbèrò.

Tí o kò bá fé lóyún sùgbón tí o rò wípé o lè ti lóyún, ìwo nìkán kó ni èyí ń selè sìí

Nínu fídíò yìí, a ó sòrò nípa bí a ti lè ní àrídájú oyún níní

Àkókó, ó se pàtàkì láti mò wípé oyún ń duro léyìn ìbálòpò nígbàtí àtò bá jáde láti okó sínú òbò.

Lílo àwon nan oyún dídènà ń ranni lówó láti dènà oyún nígbàtí a bá ní ìbálòpò

Äàmì tí ó sájú tí o tún dájú jù tí a lè fi mò bóyá oyún ti dúró ni kí a má rí nkan osù.

Tí o bá ti ní ìbálòpò tí o sì se àkíyèsí wípé? nkan osù re pé kí ó tó wá, o lè ti lóyún.

Àwon ààmì oyún ní ìwònyí kí èébì máa gbéni, orí fífó, kó máa reni, àti omú tí ó tóbi tí ó síì rò.

Tí o bá ní òkan nínú àwon ààmì wònyí, tí o kò sì rí nkan osù re, ó se é se wípé o ti lóyún.

Tí o bá rò wípé o ti lóyún, o lè ní àrídájú èyí nípa síse àyèwò ìtò re.

Àwon ohun tí a lè fi se àyèwò oyún ni a ń tà ní ilé ìtògùn àti sóòbù ìtòsí, tàbí o lè lo sí ilé ìwòsàn láti ra òkan.

Kò pi dandan kí o se àyèwò oyun kí o tó lè séyún pèlú òògùn kóró.

Tí o bá ní àwon ààmì oyún, tàbí tí àyèwò oyún tí o se bá fihàn wípé o lóyún, sùgbón tí o kò fé lóyún, o lè pinu láti sé oyún náà.

A lè séyún nípa lílo òògùn oníkóró tàbí nípa isé abe.

Mâa bá fídíò yí lo bí a ó se máa pèsè àlàyé tó pegedé àti bí a ó se máa dáhùn ìbéèrè nípa oyún sísé pèlú òògùn oníkóró sáájú òsè métàlá.

Nínu fídíò tó kàn, a ó dáhùn ìbéèrè yí, “Osù kélò ni oyún mi wà?”